Nehemiah 1:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Olúwa, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ yìí, àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ní inú dídùn láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Fún ìránṣẹ́ rẹ ní àṣeyọrí lónìí kí o sì ṣíjú àánú wò ó níwájú Ọkùnrin yìí.” Nítorí tí mo jẹ́ agbọ́tí ọba nígbà náà. Viz kapitolaYoruba Bible11 OLUWA, tẹ́tí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mo bẹ̀rù orúkọ rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, kí n sì rí ojurere ọba.” Èmi ni agbọ́tí ọba ní àkókò náà. Viz kapitolaBibeli Mimọ11 Oluwa, emi bẹ ọ, tẹ́ eti rẹ silẹ si adura iranṣẹ rẹ, ati si adura awọn iranṣẹ rẹ, ti o fẹ lati bẹ̀ru orukọ rẹ: emi bẹ ọ, ki o si ṣe rere si iranṣẹ rẹ loni, ki o si fun u li ãnu li oju ọkunrin yi. Nitori agbe-ago ọba li emi jẹ. Viz kapitola |