Juda 1:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa. Viz kapitolaYoruba Bible4 Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi. Viz kapitolaBibeli Mimọ4 Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa. Viz kapitola |