Isaiah 1:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, Ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i. Viz kapitolaYoruba Bible4 Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ, ìran oníṣẹ́ ibi; àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́! Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i. Viz kapitolaBibeli Mimọ4 A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn. Viz kapitola |