Ìfihàn 1:9 - Bibeli Mimọ9 Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi. Viz kapitolaYoruba Bible9 Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi. Viz kapitolaBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. Viz kapitola |