O. Daf 1 - Bibeli MimọAyọ̀ Tòótọ́ IWE KINNI ( O. Daf 1—41 ) 1 IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. 2 Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru. 3 Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede. 4 Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ. 5 Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo. 6 Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria