Marku 6:56 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní56 Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá. Sien die hoofstukYoruba Bible56 Níbikíbi tí ó bá wọ̀, ìbáà ṣe ní abúlé tabi ninu ìlú, ní ìgbèríko, tabi ní ọjà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá. Wọn a máa bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn ṣá lè fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án pátá ni ó mú lára dá. Sien die hoofstukBibeli Mimọ56 Nibikibi ti o ba si gbé wọ̀, ni iletò gbogbo, tabi ilu nla, tabi arọko, nwọn ngbé olokunrun kalẹ ni igboro, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, a mu wọn larada. Sien die hoofstuk |