Esteri 6:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní13 Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí Mordekai ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” Sien die hoofstukYoruba Bible13 Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.” Sien die hoofstukBibeli Mimọ13 Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan. Sien die hoofstuk |